Jóòbù 41 BMY

Ọlọ́run Ń Tẹ̀ṣíwájú Láti Pe Jóòbù Níjà

1 “Ǹjẹ́ ìwọ lè ífi ìwọ fa Lefíátanì,ọ̀nì ńlá jáde? Tàbí ìwọ lè fi okùn so ahọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀?

2 Ìwọ lè fi okùn bọ̀ ọ́ ní ímú,tàbí fi ìwọ̀ gun ní ẹ̀rẹ̀kẹ́?

3 Òun ha jẹ́ bẹ ẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀rẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí òun ha bá ọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́?

4 Òun ha bá ọ dá májẹ̀mú bí? Ìwọ óha máa mú ṣe ẹrú láéláé bí?

5 Ìwọ hà lè ba saré bí ẹni pé ẹyẹ ni,tàbí ìwọ ó dè é fún àwọn ọmọbìnrin ìránṣẹ́ rẹ̀?

6 Ẹgbẹ́ àwọn apẹja yóò ha máa tà ábí? Wọn ó ha pín láàrin àwọn oníṣòwò?

7 Ìwọ ha lè fi ọ̀kọ̀-irin awọ rẹ̀,tàbí orí rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ipẹja.

8 Fi ọwọ́ rẹ lée lára, ìwọ ó rántí ìjànáà, ìwọ kì yóò sì ṣe bẹ̀ẹ́ mọ́.

9 Kiyèsí àbá nípaṣẹ̀ rẹ ní asán; níkìkì ìrí rẹ̀ ara kì yóò ha rọ̀ ọ́ wẹ̀sì?

10 Kò sí ẹni aláyà lílé tí ó lè rusókè; Ǹjẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú mi.

11 Ta ni ó ṣáájú ṣe fún mi, tí èmi ìbáfi san-án fún un? Ohunkóhun ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run gbogbo, tèmi ni.

12 “Èmi kì yóò fi ẹ̀yà ara rẹ, tàbi ipárẹ, tàbí ìhámọ́ra rẹ tí ó ní ẹwà pamọ́.

13 Ta ni yóò lè rídìí aṣọ àpáta rẹ?Tàbí ta ni ó lè súnmọ́ ọ̀nà méjì ẹ̀yìn rẹ.?

14 Ta ni ó lè sí ìlẹ̀kùn ẹnu rẹ?Àyíká ẹ̀yin rẹ ni ìbẹ̀rù ńlá.

15 Ipẹ́ lílé ní ìgbéraga rẹ̀; ó pàdépọ̀ tímọ́tímọ́ bí àmì èdìdì.

16 Èkíní fi ara mọ́ èkejì tóbẹ́ẹ̀ tí afẹ́fẹ́kò lè wọ àárin wọn.

17 Èkíní fi ara mọ́ èkejì rẹ̀; wọ́n lẹ̀wọ́n pọ̀ tí a kò lè mọ̀ wọ́n.

18 Nípa sísin rẹ̀ ìmọ́lẹ̀ mọ́, ojú rẹ̀ asì dàbí ìpénpéjú òwúrọ̀.

19 Láti ẹnu rẹ ni ọ̀wọ́ iná ti jádewá, ìpẹ́pẹ́ iná a sì ta jáde.

20 Láti imu rẹ ni èéfín ti jáde wá,bí ẹni pé láti inú ìkòkò tí a fẹ́ iná ìféfé lábẹ́ rẹ̀.

21 Èémi rẹ̀ tinábọ ẹ̀yin, ọ̀wọ́ iná sìti ẹnu rẹ̀ jáde.

22 Ní ọrún rẹ̀ ní agbára kù sí, àtiìbànújẹ́ àyà sì padà di ayọ̀ níwájú rẹ̀.

23 Jabajaba ẹran rẹ̀ dìjọ pọ̀, wọ́nmúra gírí fún ara wọn, a kò lè sí wọn nípò.

24 Àyà rẹ̀ dúró gbagigbagi bí òkúta,àní ó le bi ìyá ọlọ.

25 Nígbà tí ó bá gbé ara rẹ̀ sókè,àwọn alágbára bẹ̀rù; nítoríìbẹ̀rù ńlá, wọ́n dààmú.

26 Ọ̀kọ̀ tàbí idà, tàbi ọfà, ẹni tí ó sáa kò lè rán an.

27 Ó ká ìrin sí bi koríko gbígbẹ àtiidẹ si bi igi híhù.

28 Ọfà kò lè mú un sá; òkútakànnakánná lọ́dọ̀ rẹ̀ dàbí àkékù koríko.

29 Ó ka ẹṣin sí bí àkékù idi koríko;ó rẹ́rin-ín sí mímì ọ̀kọ̀.

30 Òkúta mímú ń bẹ nísàlẹ̀ abẹ́ rẹ̀, ósì tẹ́ ohun mímú ṣónṣó sórí ẹrẹ̀.

31 Ó mú ibú omi hó bí ìkòkò; ó sọ̀agbami òkun dàbí kólòbó ìkunra.

32 Ó mú ipa ọ̀nà tan lẹ́yìn rẹ̀; ènìyàna máa ka ibú sí ewú arúgbó.

33 Lórí ilẹ̀ ayé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀,tí a dá láìní ìbẹ̀rù.

34 Ó bojú wo ohun gíga gbogbo, ósì nìkan já sí ọba lórí gbogboàwọn ọmọ ìgbéraga.”