Jóòbù 29 BMY

Jóòbù Rántí Ìbùkún Rẹ̀ Àtẹ̀yìnwá

1 Pẹ̀lúpẹ̀lù, Jóòbù sì tún tẹ̀ ṣíwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé:

2 “Áà! ìbá ṣe pé èmi wà bí ìgbà oṣù tíó kọjá, bí ọjọ́ tí Ọlọ́run pamímọ́;

3 Nígbà tí fìtílà rẹ tàn sí mi ní orí,àti nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ èmi rìn nínú òkùnkùn já;

4 Bí mo tirí nígbà ọ̀dọ́ mi, nígbàtí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ bùkún ilé mi

5 Nígbà tí Olódùmarè wà pẹ̀lú mi,nígbà tí àwọn ọmọ mi wà yí mi ká;

6 Nígbà tí èmi fi òrí àmọ́ n wẹ ìsísẹ̀ mi,àti tí àpata ń tú ìsàn òróró jáde fún mi wá.

7 “Nígbà tí mo jáde la àárin ìlú lọ síẹnu ibodè, nígbà tí mo tẹ́ ìtẹ́ mi ní ìgboro,

8 Nígbà náà ni àwọn ọmọkùnrin rími, wọ́n sì sápamọ́, àwọn àgbà dìde dúró ní ẹṣẹ̀ wọn;

9 Àwọn ọmọ aládé dákẹ́ ọ̀rọ̀ sí sọ,wọn a sì fí ọwọ́ wọn lé ẹnu;

10 Àwọn ọmọ ọlọ́lá dákẹ́, ahọ́n wọnsì lẹ̀mọ́ èrìgì ẹnu wọn.

11 Nígbà tí etí gbọ́, ó sì súrefún mi,àti nígbà tí ojú sì rí mi, ó jẹ́rìí mi;

12 Nítorí mo gbà talákà tí n fẹ́ ìrànlọ́wọ́,àti aláìní baba, tí kò sí olùrànlọ́wọ́ fún un

13 Ẹni tí ó ń kìlọ̀ súre fún mi, èmisì mú àyà opó kọrin fún ayọ̀.

14 Èmi sì mú òdodo wọ̀ bí aṣọ, ẹ̀tọ́mi dà bí aṣọ ìgúnwà àti adé ọba.

15 Mo ṣe ojú fún afọ́jú mo sì ṣe ẹṣẹ̀fún amúkùnún.

16 Mo ṣe baba fún talákà, mo ṣeìwádìí ọ̀ràn àjòjì tí èmi kò mọ̀ rí.

17 Mo sì ká eyín ẹ̀rẹ̀kẹ́ ìkà ènìyàn,mo sì já ohun ọdẹ náà kúrò ní eyín rẹ̀.

18 “Nígbà náà ni mo rò pé, ‘Èmi yóòkú nínú ilé mi, èmi yóò sì mú ọjọ́ mi pọ̀ sí i bí i yanrìn.

19 Gbòǹgbò mi yóò ta kan omi, ìrìyóò sì sẹ̀ ní gbogbo òru sí ara ẹ̀ka mi.

20 Ògo mi yóò wà ní ọ̀tún ní ọ̀dọ̀mi, ọrun mi sì padà di titun ní ọwọ́ mi’

21 “Èmi ni ènìyàn ń dẹtí sílẹ̀ sí, wọna sì dúró, wọn a sì dákẹ́ rọ́rọ́ ní ìmọ̀ràn mi.

22 Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ mi, wọn kò tún sọ̀rọ̀mọ́; ọ̀rọ̀ mi wọ̀ wọ́n ní etí ṣinṣin.

23 Wọn a sì dúró dè mí bí ẹni wí péwọ́n dúró fún ọ̀wọ́ òjò wọn a sìmu nínú ọ̀rọ̀ mi bí ẹní mu nínú òjò àrọ̀-kúrò.

24 Èmi sì rẹ́rìn ín sí wọn nígbà tí wọnkò bá gbà á gbọ́; ìmọ́lẹ̀ ojú mi jẹ́ iyebíye síwọn.

25 Mo la ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn, mo sìjókòó bí olóyè wọn; mo jókòó bíọba ní àárin ológun rẹ̀; mo sìrí bí ẹni tí ń tu ẹni tí ń sọ̀fọ̀ nínú.