Jóòbù 15 BMY

Élífásì Tako Ọ̀rọ̀ Jóòbù

1 Ígbà náà ní Élífásì, ará Témà, dáhùn wí pé:

2 “Ọlọ́gbọ́n a máa sọ̀rọ̀ ìmọ̀ asán, kíó sì máa fi afẹ́fẹ́ ìlà oòrun kún ara rẹ̀ nínú?

3 Òun lè máa fi àròyé sọ̀rọ̀ tí kò níèrè, tàbí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nínú èyí tí kò lè fi ṣe rere?

4 Ìwọ ṣá ìbẹ̀rù tì, ìwọ sì dí àdúràlọ́nà níwájú Ọlọ́run.

5 Nítorí pé ẹnu ara rẹ̀ ni ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀rẹ̀, ìwọ sì yàn ahọ́n alárékérekè ni ààyò.

6 Ẹnu ara rẹ̀ ni ó dá lẹ́bi, kì í ṣe èmi;àní ètè ara rẹ̀ ni ó jẹ́rìí tì ọ́.

7 “Ìwọ ha íse ọkùnrin tí a kọ́ bi? Tabìa há dá ọ ṣáájú àwọn òkè?

8 Ìwọ gburòó àsírí Ọlọ́run rí, tàbíìwọ ha dá ọgbọ́n dúró sọ́dọ̀ ara rẹ?

9 Kí ni ìwọ mọ̀ tí àwa kò mọ̀? Òyekí ní ó yé ọ tí kò sí nínú wa?

10 Eléwú ogbó àti ògbólógbòóènìyàn wà pẹ̀lú wa, tí wọ́n gbójú baba rẹ lọ.

11 Ìtùnú Ọlọ́run ha kéré lọ́dọ̀ rẹ?Ọ̀rọ̀ kan sì ṣe jẹ́jẹ́ jù lọ́dọ̀ rẹ?

12 Èéṣe ti àyà rẹ fi ń dà ọ kiri,kí ni n mú ojú rẹ se wàìwàì.

13 Tí ìwọ fi yí ẹ̀mí rẹ padà lòdì síỌlọ́run, tí ó fi ń jẹ́ ki ọ̀rọ̀kọ́rọ̀kí ó máa bọ́ ní ẹnu rẹ̀ bẹ́ẹ̀?

14 “Kí ni ènìyàn tí ó fi mọ́? Àti ẹni tía tinú obìnrin bí tí yóò fi ṣe olódodo?

15 Kíyèsí i, òun (Ọlọ́run) kògbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀,àní àwọn ọ̀run kò mọ́ ní ojú rẹ̀;

16 Ańbọ̀tórí ènìyàn, ẹni ìríra àtieléèérìí, tí ń mù ẹ̀ṣẹ̀ bi ẹní mú omi.

17 “Èmi ó fihàn ọ́: gbọ́ ti èmi; Èyí tíèmi sì rí, òun ni èmi ó sì sọ,

18 tí àwọn ọlọ́gbọ́n ti pa ní ìtàn latiọ̀dọ̀ àwọn baba wọn wá, ti wọ́n kò sì fi pamọ́,

19 Àwọn tí a fi ilẹ̀ ayé fún nìkan,àlejò kan kò sì là wọ́n kọjá.

20 Ènìyàn búburú ń ṣe làálàá, pẹ̀lúìrora, ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo, àti iyeọdún ní a dá sílẹ̀ fún aninilára.

21 Ìró ìbẹ̀rù ń bẹ ní etí rẹ̀;nínú ìrora ni apanirun yóò dìde sí i.

22 O kò gbàgbọ́ pé òun ó jáde kúrònínú òkùnkùn; a sì ṣà á sápákan fún idà.

23 Ó ń wò káàkiri fún oúnjẹ wí pé,níbo ní ó wà? Ó mọ̀ pé ọjọ́òkùnkùn súnmọ́ tòsí.

24 Ìpọ́njú pẹ̀lú ìrora ọkàn yóò mú unbẹ̀rù, wọ́n ó sì sẹ́gun rẹ̀ bi ọba ti ímúra ogun.

25 Nítorí pé ó ti nawọ́ rẹ̀ jáde lòdìsí Ọlọ́run, ó sì múra rẹ̀ le lòdì sí Olódùmáarè,

26 Ó súre, ó sì fi ẹ̀yìn giga, àní fiìké kòóko àpáta rẹ̀ tí ó nipọn kọlù ú.

27 “Nítorí tí òun fi ọ̀rá rẹ̀ bo ara rẹ̀lojú, o sì ṣe jabajaba ọ̀rá sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

28 Òun sì gbé inú ahoro ìlú ìtakété,àti nínú iléyílé tí ènìyàn kò gbémọ́, tí ó múra tán lati di àlàpà.

29 Òun kò lé ìlà, bẹ́ẹ̀ ohun ìní rẹ̀ kòlè dúró pẹ́; Bẹ́ẹ̀ kò lè mú pípé rẹ̀ dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.

30 Òun kì yóò jáde kúrò nínúòkùnkùn; ọ̀wọ́ iná ni yóò jóẹ̀ka rẹ̀, àti nípaṣẹ̀ ẹ̀mí ẹnu rẹ̀ní yóò máa kọjá lọ kúrò.

31 Kí òun kí ó má ṣe gbẹ́kẹ̀le asán,kí ó má sì ṣe tan ara rẹ̀ jẹ.Nítorí pé asán ní yóò jásí èrè rẹ̀.

32 A ó mú un ṣẹ ṣáájú pípẹ́ ọjọ́ rẹ̀,ẹ̀ka rẹ̀ kì yóò sì tutù.

33 Yóò sì gbọ̀n àìpọ́n èṣo rẹ̀ dànù bí i àjàrà,yóò sì rẹ̀ ìyanna rẹ̀ nù bí i ti igi Ólífì.

34 Nítorí pé ayọ̀ àwọn àgàbàgebèyóò túká, iná ní yóò sì jó àgọ́ àwọn tí ó fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

35 Wọ́n lóyún ìwà ìkà, wọ́n sì bíẹ̀ṣẹ̀, ikùn wọn sì pèṣè ẹ̀tàn.”