Jóòbù 28 BMY

Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n àti òye Jóòbù

1 “Nítòótọ́, koto fàdákà ń bẹ, àtiibi tí wọ́n ti máa ń da wúrà.

2 Nínú ilẹ̀ ni à ń gbé ń wa irin,bàbà ni a sì ń dà láti inú òkúta wá.

3 Ènìyàn ni ó parí òkùnkùn, ó sì ṣeàwárí òkúta òkùnkùn àti tiinú òjìji ikú sí ìhà gbogbo.

4 Wọ́n wa ihò ilẹ̀ tí ó jìn sí àwọn tíń gbé òkè, àwọn tí ẹṣẹ̀ ènìyàngbàgbé; wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀, wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀ jìnnà sí àwọn ènìyàn.

5 Bí ó ṣe ti ilẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde wá,àti ohun tí ó wà ní ìṣàlẹ̀ ni ó yí sókè bí ẹni pé iná.

6 Òkúta ibẹ̀ ni ibi òkúta Sáfírì, o sìní erùpẹ̀ wúrà.

7 Ipa ọ̀nà náà ni ẹyẹ kò mọ̀, àti ojúgúnnugún kò rí i rí;

8 Àwọn ẹrankan agbéraga kò rìn ibẹ̀rí, bẹ́ẹ̀ ni kìnnìún tí ń ké ramúramù kò kọjá níbẹ̀ rí.

9 Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé akọ òkúta, ó yí òkèńlá po láti ìdí rẹ̀ wá.

10 Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta,ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo.

11 Ó sì ṣe ìṣàn odò kí ó má ṣe kún—kún-ya, ó sì mú ohun tí ópamọ́ hàn jáde wá sí ìmọ́lẹ̀.

12 “Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wáọgbọ́n rí, níbo sì ni òye ń gbe?

13 Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.

14 Ọ̀gbun wí pé, kò sí nínú mi;omi òkun sì wí pé, kò si nínú mi.

15 A kò le è fi wúrà rà á, bẹ́ẹ̀ ni a kòle è fi òsùnwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.

16 A kò le è fi wúrà Ófírì, tàbíòkútà Óníkísì iyebíye, tàbí òkúta Sáfírì díye lé e.

17 Góòlù àti òkúta Kírísítalì kò tóẹgbẹ́rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èló wúrà ṣe pàsípààrọ̀ rẹ̀.

18 A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta Jásípérì;iye ọgbọ́n sì ju òkúta Rubì lọ.

19 Òkùta tópásì ti Kúsì kò tóẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀.

20 “Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá?Tàbí níbo ni òye ń gbé?

21 A rí i pé, ó farasinko kúrò ní ojúàwọn alààyè gbogbo, ó sì fara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run.

22 Ibi ìparun (Ábádónì) àti ikú wípé, àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀.

23 Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nàrẹ̀, òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé

24 Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé, ósì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run,

25 Láti dà òṣùwọ̀n fún afẹ́fẹ́, ó sì fiòṣùwọ̀n wọ̀n omi.

26 Nígbà tí ó pàsẹ fún òjò, tí ó sì laọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,

27 Nígbà náà ni órí i, ó sì sọ ọ́ jáde;ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí.

28 Àti fún ènìyàn ni ó wí pé,‘Kíyè sí i ẹ̀rù Olúwa èyí ni ọgbọ́n, àtiláti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.’ ”