Jóòbù 2 BMY

Ọlọ́run Gbà Fún Sàtánì Kí Ó Dán Jóòbù Wò Lẹ́ẹ̀kejì

1 Ó sì tún di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá síwájú Olúwa, Sàtánì sì wá pẹ̀lú wọn láti pe níwájú Olúwa.

2 Olúwa sì bi Sàtánì pé, Níbo ni ìwọ ti wá?Sàtánì sì dá Olúwa lóhùn pé, “Láti lọ síwá sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.”

3 Olúwa sì wí fún Sàtánì pé, “Ìwọ ha kíyèsí Jóòbù ìránṣẹ́ mi, pé, kò sí èkejì rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí ń ṣe olóòótọ́ tí ó sì dúró sinsin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì kóríra ìwà búburú, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di ìwà òtítọ́ rẹ̀ mu ṣinṣin, bí ìwọ tilẹ̀ ti dẹ mí sí i láti run-ún láìnídìí.”

4 Sàtánì sì dá Olúwa lóhùn wí pé, “Awọ fún awọ; àní ohun gbogbo tí ènìyàn ní, òun ni yóò fi ra ẹ̀mí rẹ̀.

5 Ṣùgbọ́n nawọ́ rẹ nísinsìn yìí, kí ó tọ́ egungun rẹ̀ àti ara rẹ̀, bí kì yóò sì bọ́hùn ní ojú rẹ.”

6 Olúwa sì wí fún Sàtánì pé, “Wò ó, Ó ń bẹ ní ìkàwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.”

7 Bẹ́ẹ̀ ni Sàtánì jáde lọ kúrò níwájú Olúwa, ó sì sọ Jóòbù ní oówo kíkan kíkan láti àtẹ́lẹṣẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀

8 Ó sì mú àpáàdì, ó fi ń ha ara rẹ̀, ó sì jókòó nínú eérú.

9 Nígbà náà ni aya rẹ̀ wí fún-un pé, “Ìwọ di ìwà òtítọ́ mú síbẹ̀! Bú Ọlọ́run, kí ó sì kú!”

10 Ṣùgbọ́n ó dá a lóhùn pé, “Ìwọ sọ̀rọ̀ bí ọ̀kan lára àwọn obìnrin aláìmọ́ye ti í sọ̀rọ̀; há bà! Àwa yóò ha gba ire lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí a má sì gba ibi?”Nínú gbogbo èyí, Jóòbù kò fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀.

Ọ̀rẹ́ Jóòbù Mẹ́ta

11 Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta gbúròó gbogbo ibi tí ó bá a, wọ́n wá, olúkúlùkù láti ibùjókòó rẹ̀; Élífásì, ara Témà àti Bílídádì, ara Ṣúà, àti Sófárì, ará Náámù: nítorí pé wọ́n ti dájọ́ ìpàdé pọ̀ láti bá a sọ̀fọ̀ àti láti sìpẹ̀ fún un.

12 Nígbà tí wọ́n gbójú wọn wò ní òkèrè réré, tí wọ́n kò sì mọ̀ ọ́n, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sọkún: olúkúlùkù sì fa àṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, wọ́n sì ku erùpẹ̀ sí ojú ọ̀run, wọ́n sì tẹ́ orí gbà á.

13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jòkòó tì í ní inú erùpẹ̀ ní ọjọ́ méje ti ọ̀sán ti òru, ẹnikẹ́ni kò sì bá a dá ọ̀rọ̀ kan sọ nítorí tí wọ́n ti rí i pé ìbànújẹ́ rẹ̀ pọ̀ gidigidi.