Jóòbù 18 BMY

Ìdáhùn Bílídádì

1 Ígbà náà ni Bílídádì, ará Ṣúà, dáhùn, ó sì wí pé:

2 “Nígbà wo ni ẹ̀yin yóò tó fi ìdí ọ̀rọ̀tì; ẹ rò ó, nígbẹ̀yìn rẹ̀ ni àwa ó tó máa sọ

3 Nítorí kí ni a ṣe ń kà wá sí bíẹranko, tí a sì ń kà wá si bí ẹni ẹ̀gàn ní ojú yín?

4 Ìwọ fa ara rẹ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínúìbínú rẹ̀; kí a ha kọ ayé sílẹ̀nítorí rẹ̀ bi? Tàbí kí a sí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀?

5 “Nítòótọ́ ìmọ́lẹ̀ ènìyàn búburú ni aó pa kúrò, Ọ̀wọ́ iná rẹ̀ kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀.

6 Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn nínú àgọ́rẹ̀, fìtílà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni a ó sì pa pẹ̀lú.

7 Ìrìn ẹṣẹ̀ agbára rẹ̀ yóò di fífọn;ìmọ́lẹ̀ òun tìkárarẹ̀ ni yóò bí i ṣubú.

8 Nípa ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkararẹ̀ ó ti bọ́ sínúàwọ̀n, ó sì rìn lóri okùn dídẹ.

9 Tàkúté ni yóò mú un ní gìgísẹ̀,àwọn àwọ̀n tí a dẹ yóò sì ṣẹ́gun rẹ̀.

10 A dẹkùn sílẹ̀ fún un lórí ilẹ̀, a sìwà ọ̀fìn fún un lojú ọ̀nà.

11 Ẹ̀rù ńlá yóò bà á ní ìhà gbogbo,yóò sì lé e dé ẹsẹ̀ rẹ̀.

12 Àìlera rẹ̀ yóò di pipa fún ebi,ìparun yóò dìde dúró sí i nígbà tí ó bá ṣubú.

13 Yóò jẹ ẹ̀yà ara rẹ̀; àkọ́bí ikú niyóò jẹ agbára rẹ̀ run.

14 A ó fà á tu kurò nínú àgọ́ tí ógbẹ́kẹ̀lé, a ó sì mú un tọ ọba ẹ̀rù ńlá nì lọ.

15 Yóò sì máa jókòó nínú àgọ́ rẹ̀èyí tí í ṣe tirẹ̀; ìmí ọjọ́ ni a ó fún káàkiri ibùgbé rẹ̀.

16 Gbòngbò rẹ̀ yóò gbẹ níṣàlẹ̀, a ósì ké ẹ̀ka rẹ̀ kúrò lókè.

17 Ìrántí rẹ̀ yóò parun kúrò ni ayé,kì yóò sí orúkọ rẹ̀ ní ìgboro ìlú.

18 A ó sì lée láti inú ìmọ́lẹ̀ sí inúòkùnkùn, a ó sì lé e kúrò ní ayé.

19 Kì yóò ní ọmọ tàbí ọmọ ọmọnínu àwọn ènìyàn rẹ̀, Bẹ́ẹ̀ ni kòsí ẹnikẹ́ni tí yóò kù nínú agbo ilé rẹ̀.

20 Ẹnu yóò ya àwọn ìran ti ìwọ̀oòrùn sí ìgbà ọjọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíẹ̀rù ìwárìrì ti í bá àwọn ìran ti ìlà oòrùn.

21 Nítòótọ́ irú bẹ́ẹ̀ ni ibùgbé àwọnènìyàn búburú Èyí sì ni ipò ẹni tí kò mọ̀ Ọlọ́run.”