Jóòbù 40 BMY

Jóòbù Rẹ Ara Rẹ̀ Sílẹ̀

1 Olúwa dá Jóòbù lóhùn sí pẹ̀lú, ó sì wi pé:

2 “ẹni tí ń wá ẹ̀sùn yóò bá Olódùmarè wíjọ́ bí?Ẹni tí ń bá Ọlọ́run jiyàn jẹ́ kí ó dáhùn!”

3 Nígbà náà ni Jóòbù dá Olúwalóhùn wá ó sì wí pé,

4 “Kíyèsí i, èmi kò jámọ́ ohun kankan;ohun kí ni èmi ó dà? Èmi ó fi ọwọ́ le ẹnu mi.

5 Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kòrí ìdáhùn kankan; lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì ní sọ ọ́ mọ́.”

6 Nígbà náà ní Olúwa sọ̀rọ̀ fún unláti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé:

7 “Di àmùrè gíri ní ẹgbẹ́ rẹ, èmi ó biọ léèrè, kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.

8 “Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán?Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo

9 Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run tàbí ìwọ lèfi ohùn sán àrá bí òun?

10 Fi ọlá ńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ararẹ ní ọ̀ṣọ́, tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bi ara ní aṣọ.

11 Mú ìrúnu ìbínú rẹ jáde; kíyèsígbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀

12 Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyànkí o sì rẹ ẹ sílẹ̀, kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.

13 Sin gbogbo wọn pa pọ̀ nínúerùpẹ̀, kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú

14 Nígbà náà ní èmi ó yàn ọ́ pé,ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là.

15 “Ǹjẹ́ nísinsìnyí kíyèsí Béhámótì tímo dá pẹ̀lú rẹ: òun ha máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù.

16 Wò o nísinsìnyí, agbára rẹ wà níẹ̀gbẹ́ rẹ, àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ.

17 Òun a máa jù ìru rẹ̀ bí i igikédarì; Isan itan rẹ̀ dijọ pọ̀.

18 Egungun rẹ̀ ní ògùsọ̀ idẹ;Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin.

19 Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́Ọlọ́run; ṣíbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́.

20 Nítòótọ́ òkè ńláńlá ní imu ohunjíjẹ fún un wá, níbi tí gbogboẹranko ìgbẹ́ máa siré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀

21 Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótósì,lábẹ́ èèsún àti ẹrẹ̀.

22 Igi lótósì síji wọn bò o;igi àrọ̀rọ̀ odò yí i kákiri.

23 Kíyèsí i, odò ńlá sàn jọjọ,òun kò sálọ; ó wà láìléwu bí óbá ṣe pé odò Jọ́rdánì ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀.

24 Ẹnìkan ha lè ímú u ní ojú rẹ̀, tàbía máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?