Jóòbù 6 BMY

Ìdáhùn Jóòbù

1 Jóòbù sì dáhùn ó si wí pé:

2 “Áà! à bá lè wọ̀n ìbìnújẹ́ mi nínú òṣùwọ̀n,kí a sì le gbé ọ̀fọ̀ mi lé orí òṣùwọ̀n ṣọ̀kan pọ̀!

3 Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ìbá wúwo jú iyánrìn òkun lọ:nítorí náà ni ọ̀rọ̀ mi ṣe ń tàsé

4 Nítorí pé ọfà Olódùmárè wọ̀ mi nínú,oró èyí tí ọkàn mi mú;ìpayà-ẹ̀rù Ọlọ́run dúró tì mí.

5 Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ á máa dún nígbà tí ó bá ní koríko,tàbí ọ̀dá-màlúù a máa dún sórí ìjẹ rẹ̀?

6 A ha lè jẹ ohun tí kò ní adùn ní àìní iyọ̀,tàbi adùn ha wà nínú fúnfún eyin?

7 Ohun ti ọ̀kan mi kọ̀ láti tọ́wò,òun ni ó dàbí oúnjẹ mi tí kò ní adùn.

8 “Áà! èmi ìbá lè rí ìbéèrè mi gbà;àti pé, kí Ọlọ́run lè fi ohun tí èmi ṣàfẹ́rí fún mi.

9 Àní Ọlọ́rin ìbá jẹ́ pa mí run,tí òun ì bá jẹ́ siwọ́ rẹ̀ kì ó sì ké mi kúrò.

10 Nígbà náà ní èmi ì bá ní ìtùnú síbẹ̀,àní èmi ì bá mú ọkàn mi le nínú ìbànújẹ́ mi ti kò dá ni sí:nítorí èmi kò fi ọ̀rọ̀ ẹni mímọ́ ni sin rí.

11 “Kí ní agbára mi tí èmi ó fi retí?Kí sì ní òpin mi tí èmi ó fi ní sùúrù?

12 Agbára mi iṣe agbára òkúta bí,tàbí ẹran ara iṣe idẹ?

13 Ìrànlọ́wọ́ mi kò ha wà nínú mi:ọgbọ́n ha ti sálọ kúrò lọ́dọ̀ mi bí?

14 “Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá,kí ó má ba à kọ ìbẹ̀rù Olódumáarè sílẹ̀?

15 Àwọn ará mi ṣọ̀tẹ̀ bí odò sólobí ìṣàn gúru omi odò sólo, wọ́n ṣàn kọjá lọ.

16 Tí ó dúdú nítorí omi dídì,àti níbi tí odò dídì gbé lùmọ̀ sí.

17 Nígbà kúgbà tí wọ́n bá gbóná wọn a sì yọ́ ṣànlọ,nígbà tí òòrùn bá mú, wọn a sì gbẹ kúrò ni ipò wọn.

18 Ìyà ọ̀nà wọn a sì yípadà sí apá kan,wọ́n gòkè sí ibi asán, wọ́n sì run.

19 Ẹgbẹ́ ogun Témà ń wòyeàwọn ọwọ́ àrò Sébà ń dúró dè wọ́n.

20 Wọ́n já lulẹ̀, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lée;wọ́n débẹ̀, wọ́n sì dààmú.

21 Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ẹ̀yin dàbí wọn;ẹ̀yin rí ìrẹ̀sílẹ̀ mi àyà sì fò mí.

22 Èmi ó ha wí pé, ‘Ẹ mú ohun fún mi wá,tàbí pé ẹ fún mi ní ẹ̀bùn nínú ohun ìní yín?

23 Tàbí, ẹgbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá ni,tàbí, ẹrà mí padà kúrò lọ́wọ́ alágbára nì.’?

24 “Ẹ kọ́ mi, èmi ó sì pa ẹnu mi mọ́kí ẹ sì mú mi wòye níbi tí mo gbé ti sìnà.

25 Wò ó! Bí ọ̀rọ̀ òtítọ́ ti lágbára tóṣùgbọ́n kí ni àròyé ìbàwí yín já sí?

26 Ẹ̀yin ṣè bí ẹ ó bá ọ̀rọ̀àti ohùn ẹnu tí ó takú wí tí ó dà bí afẹ́fẹ́.

27 Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba,ẹ̀yin sì da iye lé ọ̀rẹ́ yín.

28 “Nítorí náà, kí èyí kí ó tó fún yín.Ẹ má wò mi! Nitorí pé ó hàn gbangba pé:Ní ojú yín ni èmi kì yóò sèké.

29 Èmi ń bẹ̀ yín, ẹ padà, kí ó má sì ṣe jásí ẹ̀ṣẹ̀;àní, ẹ sì tún padà, àre mi ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí.

30 Àìṣedédé ha wà ní ahọ́n mi?Ǹjẹ́ ìtọ́wò ẹnu mi kò kúkú le mọ ohun ti ó burú jù?