1 “Ò ó, ojú mi ti rí gbogbo èyí rí,Etí mí sì gbọ́, ó sì ti yé e.
2 Ohun tí ẹ̀yin mọ̀, èmi mọ̀ pẹ̀lú,èmi kò rẹ̀yìn sí yin.
3 Nítòótọ́ èmi ó bá Olódumárèsọ̀rọ̀, Èmi sì ń fẹ́ bá Ọlọ́run sọ àsọyé.
4 Èyin ni oníhùmọ̀ èké, oníṣègùnlásán ni gbogbo yín
5 Áà! ẹ̀yin kì bá kúkú dákẹ́! Èyi nikì bá sì ṣe ọgbọ́n yín.
6 Ẹ gbọ́ àwíyé mi nísinsìn yìí, Ẹ sìfetísilẹ̀ sí àròyé ètè mi.