19 Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sìmú omi ṣàn bo ohun tí ó hù jáde lóri ilẹ̀,ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo.
20 Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjálọ; Ìwọ pa awọ oju rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò.
21 Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òunkò sì mọ̀; wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀,òun kò sì kíyèsìí lára wọn.
22 Ṣùgbọ́n ẹran ara rẹ̀ ni yóò ríìrora. Ọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀.”