3 Ìwọ sì ń síjú rẹ wò irú èyí ni?Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ?
4 Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ látiinú àìmọ́ jáde wá? Kò sí ẹnìkan!
5 Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀, ìye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;Ìwọ ti pàlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀.
6 Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lèsinmi, títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.
7 “Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a báké e lulẹ̀, pé yóò sì tún ṣọ, àtipé ẹ̀ka rẹ̀ titun kì yóò dá.
8 Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀,tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀;
9 Síbẹ̀ nígbà tí ó bá gboorùn omi,yóò sọ yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.