6 Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lèsinmi, títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.
7 “Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a báké e lulẹ̀, pé yóò sì tún ṣọ, àtipé ẹ̀ka rẹ̀ titun kì yóò dá.
8 Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀,tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀;
9 Síbẹ̀ nígbà tí ó bá gboorùn omi,yóò sọ yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.
10 Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù;Àní ènìyàn jọwọ́ ẹ̀mi rẹ̀ lọ́wọ́: Òun ha dà?
11 “Bí omi tí i sàn nínú ipa odò,tí odò sì ífà tí sì ígbẹ,
12 bẹ́ẹ̀ ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́;títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́,wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.