19 Ǹjẹ́ nísinsinyí kíyèsí i, ẹlẹ́rìí miń bẹ ní ọ̀run, ẹ̀rí mi sì ń bẹ lókè ọ̀run.
20 Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣẹ̀sín,ṣùgbọ́n ojú mi ń da omijé sọ́dọ̀ Ọlọ́run;
21 Ìbáṣe pé ẹnìkan le è máa ṣe alágbàwífún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọ́run,bí ènìyàn kan ti íṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀.
22 “Nítorí nígbà tí iye ọdun díẹ̀ rékọjátán, nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà bọ̀.