7 Ojú mí ṣú bàìbàì nítorí ìbìnújẹ́,gbogbo ẹ̀yà ara mi sì dàbí òjìji.
8 Àwọn olódodo yóò yanu sí èyí,ẹni aláìsẹ̀ sì bínú sí àwọn àgàbàgebè.
9 Olódodo pẹ̀lú yóò di ọ̀nà rẹ̀ mú,àti ọlọ́wọ́ mímì yóò máa lera síwájú.
10 “Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti gbogbo yín, ẹ yípadà, kí ẹ sì tún bọ̀ nísinsin yìí;èmi kò le rí ọlọgbọ́n kan nínú yín.
11 Ọjọ́ tí èmi ti kọjá, ìro mi ti fàjá, àní ìro ọkàn mi.
12 Àwọn ènìyàn wọn yí ìsọ́ òru diọ̀sán; wọ́n ní, ìmọ́lẹ̀ súnmọ́ ibi tí òkùnkùn dé.
13 Bí mo tilẹ̀ ní ìrètí, ipò òku ní ilémi; mo ti tẹ́ ìbùsùn mi sínú òkùnkùn.