18 Àní àwọn ọmọdé kùnrin fi míṣẹ̀sín: Mo dìde, wọ́n sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi.
19 Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mikórìíra mi, àwọn olùfẹ́ mi sì kẹ̀yìndà mí.
20 Egungun mi lẹ̀ mọ́ ara mi àti mọ́ẹran ara mi, mo sì bọ́ pẹ̀lú awọ eyín mi.
21 “Ẹ ṣáànú fún mi, ẹ ṣàánú fún mi,ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí ọwọ́ Ọlọ́run ti bà mí.
22 Nitorí kí ni ẹ̀yin ṣe lépa mi bíỌlọ́run, tí ẹran ara mi kò tẹ́ yín lọ́rùn?
23 “Áà! Ìbáṣe pé a le kọ̀wé ọ̀rọ̀ minísinsìn yìí, ìbáṣepé a le dà á sínú ìwé!
24 Kí a fi kálàmú irin àti ti òjé kọwọ́n sínú àpáta fún láéláé.