7 “Kiyè sì í, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára;’ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi;mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdajọ́.
8 Ó sọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le èkọjá, Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi.
9 Ó ti bọ́ ògo mi,ó sì sí adé kúrò ní orí mi.
10 Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo,ẹ̀mí sì pin; ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi.
11 Ó sì tinábọ ìbínú rẹ̀ sími,ó sì kà mí sí bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀.
12 Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ sì dàpọ̀ sí mi, wọ́nsì mọ odi yí mi ká, wọ́n sì yíàgọ́ mi ká.
13 “Ó mú àwọn arákùnrin mi jìn nàsí mi réré, àti àwọn ojúlùmọ̀ midi àjèjì sí mi pátapáta.