5 Pé, orin ayọ̀ ènìyàn búburú, ìgbàkúkúrú ni, àti pé, ní ìṣẹ́jú kan ní ayọ̀ àgàbàgebè?
6 Bí ọláńlá rẹ̀ tilẹ̀ gòkè dé ọ̀run, tiori rẹ̀ sì kan àwọsánmà;
7 Ṣùgbọ́n yóò ṣègbé láéláé bí ìgbẹ́ara rẹ̀; àwọn tí ó ti rí i rí yóò wí pé, ‘Òun ha dà?’
8 Yóò fò lọ bí àlá, a kì yóò sì rí i,àní a ó lé e lọ bi ìran òru.
9 Ojú tí ó ti rí i rí kì yóò sì rí i mọ́,bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kì yóò sì ri i mọ́.
10 Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wá àti ríojú-rere lọ́dọ̀ talákà, ọwọ́ rẹ̀ yóò sì kó ọrọ̀ wọn padà.
11 Egungun rẹ̀ kún fún agbára ìgbàèwe rẹ̀, tí yóò bá a dùbúlẹ̀ nínú erùpẹ̀.