5 Ẹ wò mí fín, kí ẹnu kí ó sì yà yín,kí ẹ sì fi ọwọ́ lé ẹnu yín.
6 Àní nígbà tí mo rántí, ẹ̀rù bà mí,ìwárìrì sì mú mi lára.
7 Nítorí kí ní ènìyàn búburú fi wà níayé, tí wọ́n gbó, àní tí wọ́n di alágbára ní ipa?
8 Irú ọmọ wọn fi ìdí kalẹ̀ ní ojúwọn pẹ̀lú wọn, àti ọmọ-ọmọ wọn ní ojú wọn.
9 Ilé wọn wà láìní ewu àti ẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ni ọ̀pá iná Ọlọ́run kò sí lára wọn.
10 Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì ísìíṣe; abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun;
11 Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọnwẹ́ẹ́wẹ́ẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jó kiri.