15 Àwọn tí ó kú nínú tirẹ̀ ni a ósìnkú nínú àjàkálẹ̀-àrùn: àwọnopó rẹ̀ kì yóò sì sunkún fún wọn.
16 Bí ó tilẹ̀ kó fàdákà jọ bí erùpẹ̀, tíó sì dá aṣọ jọ bí amọ̀;
17 Àwọn ohun tí ó tò jọ àwọnolóòótọ́ ni yóò lò ó; àwọnaláìṣẹ̀ ni yóò sì pín fàdákà rẹ̀.
18 Òun kọ́ ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí kòkòrò aṣọ,àti bí ahéré tí olùsọ́ kọ́.
19 Ọlọ́rọ̀ yóò dùbúlẹ̀, ṣùgbọ́n òun kìyóò tún ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́; ó síjú rẹ̀, òun kò sì sí.Nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀,gbogbo rẹ̀ a lọ
20 Ẹ̀rù ńlá bàá bí omi ṣíṣàn;ẹ̀fúùfù ńlá jí i gbé lọ ní òru.
21 Ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn gbé e lọ, òun sìlọ; àti bí ìjì ńlá ó sì fà á kúrò ní ipò rẹ̀.