12 “Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wáọgbọ́n rí, níbo sì ni òye ń gbe?
13 Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.
14 Ọ̀gbun wí pé, kò sí nínú mi;omi òkun sì wí pé, kò si nínú mi.
15 A kò le è fi wúrà rà á, bẹ́ẹ̀ ni a kòle è fi òsùnwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.
16 A kò le è fi wúrà Ófírì, tàbíòkútà Óníkísì iyebíye, tàbí òkúta Sáfírì díye lé e.
17 Góòlù àti òkúta Kírísítalì kò tóẹgbẹ́rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èló wúrà ṣe pàsípààrọ̀ rẹ̀.
18 A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta Jásípérì;iye ọgbọ́n sì ju òkúta Rubì lọ.