8 Kí àwọn tí í fi ọjọ́ gégùn-ún kí o fi gégùn-ún,tí wọ́n mura tán láti ru Léfíátánì sókè.
9 Kí ìràwọ̀ òféfé ọjọ́ rẹ̀ kí ó ṣókùnkùn;kí ó má wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó máa mọ́ síi,bẹ́ẹ̀ ni kí ó má ṣe rí àfẹ̀rẹ̀mọ́jú mọ́
10 Nítorí tí kò sé ìlẹ̀kùn inú ìyá mi,bẹ́ẹ̀ ni kò pa ìbànújẹ́ rẹ́ ní ojú mi.
11 “Èéṣe tí èmi kò fi kú láti inú wá,tàbí tí èmi kò fi pín ẹ̀mí ní ìgbà tí mo ti inú jáde wá?
12 Èéṣe tí eékún wá pàdé mi,tàbí ọmú tí èmi yóò mu?
13 Ǹjẹ́ nísinsìn yìí èmi ìbá ti dúbúlẹ̀ jẹ́ẹ́;èmi a sì dákẹ́, èmi ìbá ti sùn ǹjẹ́ èmi ìbá ti sinmi
14 pẹ̀lú àwọn ọba àti ìgbìmọ̀ ayétí ìmọ́lẹ̀ takété fún ara wọn.