23 Nítorí pé ìparun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́runwá ni ẹ̀rù-ńlá fún mi, àti nitorí Ọláńlá rẹ̀ èmi kò le è dúró.
24 “Bí ó bá ṣe pé mo fi wúrà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé mi,tàbí tí mo bá wí fún fàdákà dídára pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi;’
25 Bí mo bá yọ̀ nítorí ọrọ̀ mí pọ̀, àtinítorí ọwọ́ mi dẹ lọ́pọ̀lọpọ̀;
26 Bí mo bá bojú wo oòrùn nígbà tíń ràn, tàbí òṣùpá tí ń ràn nínú ìtànmọ́lẹ̀,
27 Bí a bá tàn ọkàn mi jẹ: Láti fíẹnu mi kò ọwọ́ mi:
28 Èyí pẹ̀lú ni ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn Onidàájọ́ níbẹ̀wò. Nítorí pé èmí yóò jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run tí ó wà lókè.
29 “Bí ó bá ṣepé mo yọ̀ sì ìparun ẹnití ó korìíra mi. Tàbí bí mo bá sì gbéra sókè, nígbà tí ibi bá a.