3 Kò ṣe pé àwọn ènìyàn búburú niìparun wà fún, àti àjàkálẹ̀àrùn fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀?
4 Òun kò ha ri ipa ọ̀nà mi, òun kòha sì ka gbogbo ìṣíṣẹ̀ mi?
5 “Bí ó bá ṣepé èmi bá fi àìṣòótọ́ rìn,tàbí tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn;
6 (Jẹ́ kí Ọlọ́run wọ̀n mí nínú ìwọ̀nòdodo, kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.)
7 Bí ẹṣẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà, tíàyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi, tàbíbí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀mọ́ mi ní ọwọ́,
8 Ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmìírànkí ó sì mújẹ, àní kí a fa irú ọmọ mi tu.
9 “Bí àyà mi bá di fífà sípasẹ̀ obinrin kan,tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu ọ̀nà ilé aládùúgbò mi,