6 (Jẹ́ kí Ọlọ́run wọ̀n mí nínú ìwọ̀nòdodo, kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.)
7 Bí ẹṣẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà, tíàyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi, tàbíbí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀mọ́ mi ní ọwọ́,
8 Ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmìírànkí ó sì mújẹ, àní kí a fa irú ọmọ mi tu.
9 “Bí àyà mi bá di fífà sípasẹ̀ obinrin kan,tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu ọ̀nà ilé aládùúgbò mi,
10 Ṣùgbọ́n kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fúnẹlòmíràn, kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀.
11 Nítorí pé yóò jẹ́ ohun ìtìjú àníẹ̀ṣẹ̀ tí a ó ṣe onídàájọ́ rẹ̀
12 Nítorí pé iná ní èyí tí ó jó dé ibiìparun, tí ìbá sì fa gbòǹgbòohun ìbísí mi gbogbo tu.