1 Nígbà náà ni Élíhù dáhùn, ó sì wí pé:
2 “Ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,kí ẹ sì fi etí sílẹ̀ sí mi ẹ̀yin tí ẹ ní ìmòye.
3 Nítorí pé etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò,bí adùn ẹnu ti ń tọ́ oúnjẹ wò.
4 Ẹ jẹ́ kí a ṣà ẹ̀tọ́ yàn fún ara wa;ẹ jẹ́ kí a mọ ohun tí ó dára láàrin wa.
5 “Nítorí pé Jóòbù wí pé, ‘Aláìlẹ́sẹ̀ ni èmi;Ọlọ́run sì ti gba ìdájọ́ mi lọ.
6 Èmi ha purọ́ sí ẹ̀tọ́ mi bí,bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjẹ̀bi, ọfà rẹ̀ kò níàwòtán dídì ọgbẹ́.’