12 Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò hùwàkúwà;bẹ́ẹ̀ ni Olódùmarè kì yóò yí ìdájọ́ po.
13 Ta ni ó yàn ań lórí, tàbí ta ni ófi gbogbo ayé lée lọ́wọ́?
14 Bí ó bá gbé ayé rẹ̀ lé kìkì ara rẹ̀tí ó sì gba ọkàn rẹ̀ àti ẹ̀mí rẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,
15 gbogbo ènìyàn ni yóò parun pọ̀,ènìyàn a sì tún padà di erùpẹ̀.
16 “Ǹjẹ́ nisinsìnyí, bí ìwọ bá ní òye, gbọ́ èyí;fetísí ohùn ẹnu mi.
17 Ẹni tí ó kóríra òtítọ́ ha le iṣe olóríbí? Ìwọ ó hà sì dá olóótọ́ àti ẹni ńlá lẹ́bi?
18 O ha tọ́ láti wí fún ọba pé, ènìyàn búburú ní ìwọ,tàbí fún àwọn ọmọ aládé pé, ìkà ni ẹ̀yin;