15 gbogbo ènìyàn ni yóò parun pọ̀,ènìyàn a sì tún padà di erùpẹ̀.
16 “Ǹjẹ́ nisinsìnyí, bí ìwọ bá ní òye, gbọ́ èyí;fetísí ohùn ẹnu mi.
17 Ẹni tí ó kóríra òtítọ́ ha le iṣe olóríbí? Ìwọ ó hà sì dá olóótọ́ àti ẹni ńlá lẹ́bi?
18 O ha tọ́ láti wí fún ọba pé, ènìyàn búburú ní ìwọ,tàbí fún àwọn ọmọ aládé pé, ìkà ni ẹ̀yin;
19 Ańbọ̀tórí fún ẹni tí kì í ṣójúṣàájú àwọn ọmọ-aládétàbí tí kò kà ọlọ́rọ̀ sí talákà lọ.Nítorí pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn í ṣe?
20 Ní ìṣẹ́jú kán ni wọn ó kú, láàrin ọ̀gànjọ́àwọn ènìyàn á sì di yíyọ́, wọn a sì kọjá lọ;A sì mú àwọn alágbára kúrò láìsí ọwọ́ ènìyàn níbẹ̀.
21 “Nítorí pé ojú rẹ̀ ń bẹ ní ipa-ọ̀nàènìyàn, òun sì rí ìrìn rẹ̀ gbogbo.