6 Èmi ha purọ́ sí ẹ̀tọ́ mi bí,bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjẹ̀bi, ọfà rẹ̀ kò níàwòtán dídì ọgbẹ́.’
7 Ọkùnrin wo ni ó dàbí Jóòbù,tí ń mu ẹ̀gàn bí ẹní mú omi?
8 Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ósì ń bá àwọn ènìyàn búburú rìn.
9 Nítorí ó sá ti wí pé,‘Èrè kan kò sí fún ènìyàn,tí yóò fí máa ṣe inú dídùn sí Ọlọ́run.’
10 “Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ fetí sílẹ̀ sí miẹ fi etí sí mi ẹ̀yin ènìyàn amòye:Ódodi fún Ọlọ́run ti ìbá fi hùwà búburú àti fúnOlódùmárè, tí yóò fí ṣe àìṣedéédéé!
11 Nítorí pé ó ń sá fún ènìyàn fúnohun tí a bá ṣe, yóò sì múolúkúlùkù kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ipa ọ̀nà rẹ̀.
12 Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò hùwàkúwà;bẹ́ẹ̀ ni Olódùmarè kì yóò yí ìdájọ́ po.