1 Elíhù sì wí pe:
2 “Ìwọ rò pé èyí ha tọ́, tí ìwọ wí pé,òdodo mi ni èyí níwájú Ọlọ́run?
3 Nítorí tí ìwọ wí pé èrè kí ní yóòjá sí fún ọ, tàbí èrè kí ni èmi yóò fi jẹ́ ju èrè ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ.
4 “Èmi ó dá ọ lóhùn àti àwọn ẹgbẹ́ rẹpẹ̀lú rẹ.
5 Ṣíjú wo ọ̀run; kí o rí i, ki o sìbojúwo àwọ̀sánmọ̀ tí ó ga jù ọ lọ
6 Bí ìwọ bá sẹ̀ kí ni ìwọ fi sẹ̀ sí? Tàbíbí àìṣedéédéé rẹ di púpọ̀, kí ni ìwọ fi èyí nì ṣe sí i?
7 Bí ìwọ bá sì ṣe olódodo, kí ni ìwọfí fún u, tàbí kí ni òun rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá?