8 Ìwà búburú rẹ ni fún ènìyàn bíìwọ; òdodo rẹ sì ni fún ọmọ ènìyàn.
9 “Nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìninilára, wọ́n múni kígbe; wọ́n kigbe nípa apá àwọn alágbára.
10 Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó wí pé, ‘Níboni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá mi wà tí ó sì fi orin fún mi ní òru;
11 Tí òun kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ jù àwọnẹranko ayé lọ, tí ó sì mú wagbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ?’
12 Nígbà náà ni wọ́n ń ké ṣùgbọ́nỌlọ́run kò dáhùn nítorí ìgbéraga ènìyàn búburú.
13 Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò gbọ́ asán;bẹ́ẹ̀ ní Olódùmarè kì yóò kà á sí.
14 Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ìwọ wí pé ìwọ kì írí i, ọ̀rọ̀ ìdájọ́, ń bẹ níwájú rẹ,ẹni tí ìwọ sì gbọdọ̀ dúró dè.