2 “Fún mi láyè díẹ̀ èmi ó sì fi hàn ọ́nítorí ọ̀rọ̀ sísọ ní ó kún fún Ọlọ́run.
3 Èmi ó mú ìmọ̀ mi ti ọ̀nà jínjìn wá,èmi ó sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi.
4 Rí i dájú pé ọ̀rọ̀ mi kì yóò ṣèkénítòótọ́; ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.
5 “Kíyèsí i, Ọlọ́run ni alágbára, kò sìgàn ènìyàn; ó ní agbára ní ipá àti òye.
6 Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú síṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà.
7 Òun kì ímú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo,ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́nwà lórí ìtẹ́; Àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè.
8 Bí ó bá sì dè wọ́n nínú àbà, tí asì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n,