1 Ígbà náà ní Olúwa dá Jóòbù lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé:
2 “Ta ni èyí tí ń fi ọ̀rọ̀ àìní ìgbirò ṣuìmọ̀ ní òkùnkùn?
3 Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bíọkùnrin nísinsin yìí, nítorí péèmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ kí o sì dámi lóhùn.
4 “Níbo ni ìwọ wà nígbà ti mo fiìpìnlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Wí bí ìwọ bá mòye.
5 Ta ni ó fi ìwọ̀ rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọbá mọ̀ ọ́n? Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ?
6 Lórí ibo ni a gbé kan ìpìnlẹ̀ rẹ̀mọ́, tàbí ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀,
7 Nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀jùmọ̀ Kọrin pọ̀, tí gbogbo àwọn áńgẹ́lì hó ìhó ayọ̀?