13 Kí ó lè di òpin ilẹ̀ ayé mú, ki a lègbọ́n àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú rẹ̀?
14 Kí ó yí padà bí amọ̀ fún èdìdìamọ̀, kí gbogbo rẹ̀ kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni pé nínú aṣọ ìgúnwà.
15 A sì fa ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn kúròlọ́dọ̀ ènìyàn búburú, apá gíga yóò sì ṣẹ́.
16 “Ìwọ ha wọ inú ìsun òkun lọ rí bí?Ìwọ sì rìn lórí ìsàlẹ̀ ibú ńlá?
17 A ha sílẹ̀kùn ikú sílẹ̀ fún ọ ríbí, ìwọ sì rí ilẹ̀kùn òjìji òkú?
18 Ìwọ mòye ibú ayé bí? Sọ bí ìwọbá mọ gbogbo èyí.
19 “Ọ̀nà wo ni ìmọ́lẹ̀ ń gbé? Bí óṣe ti òkùnkùn, níbo ni ipò rẹ̀,