15 A sì fa ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn kúròlọ́dọ̀ ènìyàn búburú, apá gíga yóò sì ṣẹ́.
16 “Ìwọ ha wọ inú ìsun òkun lọ rí bí?Ìwọ sì rìn lórí ìsàlẹ̀ ibú ńlá?
17 A ha sílẹ̀kùn ikú sílẹ̀ fún ọ ríbí, ìwọ sì rí ilẹ̀kùn òjìji òkú?
18 Ìwọ mòye ibú ayé bí? Sọ bí ìwọbá mọ gbogbo èyí.
19 “Ọ̀nà wo ni ìmọ́lẹ̀ ń gbé? Bí óṣe ti òkùnkùn, níbo ni ipò rẹ̀,
20 Tí ìwọ í fi mú un lọ síbi àlá rẹ̀, tíìwọ ó sì le mọ ipa ọ̀nà lọ sínú ilé rẹ̀?
21 Ìwọ mọ èyí, nitorí nígbà náà nia bí ọ? Iye ọjọ́ rẹ sì pọ̀.