31 “Ìwọ ha le fi ọ̀já de àwọn ìràwọ̀Píléyádè dáradára? Tàbí ìwọ le tún di Ìràwọ̀ Óríónù?
32 Ìwọ le mú àwọn àmì méjìlá ìràwọ̀ Másárótì jáde wá nígbà àkókò wọn?Tàbí ìwọ le ṣe amọ̀nà Béárì pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀?
33 Ǹjẹ́ ìwọ mọ ìlànà ọ̀run?Ìwọ le fi ìjọba Ọlọ́run lélẹ̀ lórí ayé?
34 “Ìwọ le gbé ohùn rẹ sókè déàwọ̀sánmọ̀, kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi kí ó lè bò ọ́?
35 Ìwọ le rán mọ̀nàmọ́ná kí wọn kíó le lọ, ní ọ̀nà wọn kí wọn kí ósì wí fún wọn pé, àwa nìyí?
36 Ta ni ó fi ọgbọ́n pamọ́ sí ayétàbí tí ó fi òye sínú ọkàn?
37 Ta ni ó fi ọgbọ́n ka iye àwọ̀sánmọ̀? Ta ni ó sì mú ìgò ọ̀run dà jáde,