33 Ǹjẹ́ ìwọ mọ ìlànà ọ̀run?Ìwọ le fi ìjọba Ọlọ́run lélẹ̀ lórí ayé?
34 “Ìwọ le gbé ohùn rẹ sókè déàwọ̀sánmọ̀, kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi kí ó lè bò ọ́?
35 Ìwọ le rán mọ̀nàmọ́ná kí wọn kíó le lọ, ní ọ̀nà wọn kí wọn kí ósì wí fún wọn pé, àwa nìyí?
36 Ta ni ó fi ọgbọ́n pamọ́ sí ayétàbí tí ó fi òye sínú ọkàn?
37 Ta ni ó fi ọgbọ́n ka iye àwọ̀sánmọ̀? Ta ni ó sì mú ìgò ọ̀run dà jáde,
38 Nígbà tí erupẹ̀ di líle, àtiògúlùtú dípò?
39 “Ìwọ ha dẹ ọdẹ fún abo kìnnìún bí?Ìwọ ó sì tẹ ebi ẹgbọ̀rọ̀ kìnnìún lọ́rùn,