7 Nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀jùmọ̀ Kọrin pọ̀, tí gbogbo àwọn áńgẹ́lì hó ìhó ayọ̀?
8 “Tàbí ta ni ó fi ìlẹ̀kùn sé omi òkunmọ́, nígbà tí ó ya padà bí ẹni pé ó ti inú jáde wá,
9 Nígbà tí mo fi àwọ sánmọ̀ ṣe aṣọrẹ̀, tí mo sì fi òkùnkùn biribiri se ọ̀já ìgbà nú rẹ̀,
10 Nígbà tí mo ṣe òpin fún-un, tímo sì se bèbè àti ìlẹ̀kùn,
11 Tí mo sì wí pé níhìn-ín ni ìwọ ó dé,kí o má sì rékọjá, níhìn-ín sì ni ìgbéraga rẹ yóò gbé dúró mọ?
12 “Ìwọ pàṣẹ fún òwúrọ̀ láti ìgbàọjọ́ rẹ̀ wá ìwọ sì mú ìlà oòrùn mọ ipò rẹ̀,
13 Kí ó lè di òpin ilẹ̀ ayé mú, ki a lègbọ́n àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú rẹ̀?