7 Ó rẹ́rìnín sí ariwo ìlú, bẹ́ẹ̀ niÒun kò sì gbọ́ igbe darandaran.
8 Orí àtòlé òkè ńlá ni ibùjókòó rẹ̀,Òun asì má a wá ewé tútù gbogbo rí.
9 “Àgbáǹréré ha jẹ́ sìn ọ́ bí? Tàbí,ó jẹ́ dúró ní ibùjẹ ẹran rẹ ní òru?
10 Ìwọ le fi òkò tata de àgbáǹrérénínú aporo? Tàbí ó jẹ́ máa faìtulẹ̀ nínú aporo oko tọ̀ ọ́ lẹ́yìn?
11 Ìwọ ó gbẹ́kẹ̀ lée nítorí agbára rẹ̀pọ̀ ìwọ ó sì fi iṣẹ́ rẹ lé e lọ́wọ́?
12 Ìwọ le gbẹ́kẹ̀ le pé, yóò mú èsooko rẹ̀ wá sílé, àti pé yóò sì kó ọ jọ sínu àká rẹ?
13 “Ìyẹ́ abo ògòǹgò ń fi ayọ̀ fì;Ṣùgbọ́n a kò le fi àká we ara wọn ní ìyẹ́ àti ìhùhù