3 Fi idẹ ṣe ìkòkò láti máa kó eérú orí pẹpẹ sí, fi idẹ ṣe ọkọ́, àwo kòtò, ọ̀kọ̀ tí wọ́n fi ń gún ẹran ẹbọ ati àwo ìfọnná, idẹ ni kí o fi ṣe gbogbo àwọn ohun èlò pẹpẹ náà.
4 Idẹ ni kí o fi ṣe asẹ́ ààrò rẹ̀, kí o sì ṣe òrùka idẹ mẹrin, ọ̀kọ̀ọ̀kan sí igun mẹrẹẹrin asẹ́ náà.
5 Ti asẹ́ idẹ náà bọ abẹ́ etí pẹpẹ, tí yóo fi jẹ́ pé asẹ́ náà yóo dé agbede meji pẹpẹ náà sísàlẹ̀.
6 Fi igi akasia ṣe ọ̀pá pẹpẹ, kí o sì yọ́ idẹ bo ọ̀pá náà.
7 Kí o ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, tí ọ̀pá yóo fi wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji pẹpẹ náà nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gbé e.
8 Fi pákó ṣe pẹpẹ náà, kí o sì jẹ́ kí ó jin kòtò, bí mo ti fi hàn ọ́ ní orí òkè, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí o ṣe é.
9 “Ṣe àgbàlá kan sinu àgọ́ náà. Aṣọ ọ̀gbọ̀ ni kí o fi ṣe aṣọ títa apá gúsù àgbàlá náà, kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ,