4 Níwọ̀n ìgbà tí o ti mú ọkàn wọn yigbì sí ìmọ̀,nítorí náà, o kò ní jẹ́ kí wọ́n borí.
5 Bí ẹnìkan bá hùwà ọ̀dàlẹ̀, tí ó ṣòfófó àwọn ọ̀rẹ́,kí ó lè pín ninu ohun ìní wọn,àwọn ọmọ olúwarẹ̀ yóo jìyà.
6 O ti sọ mí di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn eniyan,mo di ẹni tí à ń tutọ́ sí lára.
7 Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì,gbogbo ẹ̀yà ara mi dàbí òjìji.
8 Èyí ya àwọn olódodo lẹ́nu,aláìlẹ́bi sì dojú kọ ẹni tí kò mọ Ọlọrun.
9 Sibẹsibẹ olódodo kò fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀,ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́ sì ń lágbára sí i.
10 Ṣugbọn ní tiyín, bí ẹ tilẹ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ,n kò ní ka ẹnikẹ́ni kún ọlọ́gbọ́n láàrin yín.