5 Bí ẹ bá rò pé ẹ sàn jù mí lọ,tí ẹ sì rò pé ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi ni ìdààmú mi,
6 ẹ mọ̀ dájú pé Ọlọrun ni ó dá mi lẹ́bi,tí ó sì fi àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.
7 Mò ń kérora pé wọ́n dá mi lóró,ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn;mo pariwo, pariwo,ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dìde láti ṣe ẹ̀tọ́.
8 Ọlọrun ti dí ọ̀nà mọ́ mi, kí n má baà kọjá,ó mú ọ̀nà mi ṣókùnkùn.
9 Ó bọ́ ògo mi kúrò,ó sì gba adé orí mi.
10 Ó ba ayé mi jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà,ó sì ti parí fún mi,ó fa ìrètí mi tu bí ẹni fa igi tu.
11 Ibinu rẹ̀ ń jó mi bí iná,ó kà mí kún ọ̀tá rẹ̀.