4 Ṣé o kò mọ̀ bẹ́ẹ̀ láti ìgbà àtijọ́,láti ìgbà tí wọ́n ti dá eniyan sórí ilẹ̀ ayé,
5 pé bí inú eniyan burúkú bá ń dùn,tí ẹni tí kò mọ Ọlọrun bá ń yọ̀, fún ìgbà díẹ̀ ni.
6 Bí ìgbéraga rẹ̀ tilẹ̀ ga, tí ó kan ọ̀run,tí orí rẹ̀ kan sánmà,
7 yóo ṣòfò títí lae bí ìgbọ̀nsẹ̀ ara rẹ̀,àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́n yóo bèèrè pé, ‘Níbo ló wà?’
8 Yóo parẹ́ bí àlá,yóo sì di àwátì,yóo pòórá bí ìran tí a rí lóru.
9 Ojú tí ó ti ń rí i tẹ́lẹ̀ kò ní rí i mọ́,ààyè rẹ̀ yóo sì ṣófo.
10 Àwọn ọmọ rẹ̀ yóo máa wá ojurere àwọn aláìní,wọn yóo sì san ohun tí baba wọn gbà lọ́wọ́ aláìní pada.