9 Ojú tí ó ti ń rí i tẹ́lẹ̀ kò ní rí i mọ́,ààyè rẹ̀ yóo sì ṣófo.
10 Àwọn ọmọ rẹ̀ yóo máa wá ojurere àwọn aláìní,wọn yóo sì san ohun tí baba wọn gbà lọ́wọ́ aláìní pada.
11 Bí ó tilẹ̀ dàbí ọ̀dọ́, tí ó lágbára,sibẹ yóo lọ sí ibojì, yóo sì di erùpẹ̀.
12 Bí ọ̀rọ̀ ìkà tilẹ̀ dùn ní ẹnu rẹ̀,tí ó sì fi pamọ́ sí abẹ́ ahọ́n rẹ̀,
13 bí ó tilẹ̀ lọ́ra láti sọ ọ́ jáde,tí ó pa ẹnu mọ́,
14 sibẹsibẹ oúnjẹ rẹ̀ a máa dà á ninu rú,ó sì ti dàbí oró ejò paramọ́lẹ̀ ninu rẹ̀.
15 Gbogbo owó tí ó kó jẹ ni ó tún ń pọ̀ jáde;Ọlọrun ní ń pọ̀ wọ́n jáde ninu ikùn rẹ̀.