15 Àwọn ọmọ tí wọn bá gbẹ̀yìn rẹ̀,àjàkálẹ̀ àrùn ni yóo pa wọ́n,àwọn opó wọn kò sì ní ṣọ̀fọ̀ wọn.
16 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń kó fadaka jọ bí erùpẹ̀,tí ó sì to aṣọ jọ bí amọ̀;
17 olódodo ni yóo wọ aṣọ tí ó bá kó jọ,àwọn aláìṣẹ̀ ni yóo pín fadaka rẹ̀.
18 Ilé tí ó kọ́ dàbí òwú aláǹtakùn,àní bí àgọ́ àwọn tí wọn ń ṣọ́nà.
19 A ti máa wọlé sùn pẹlu ọrọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn kò ní rí bẹ́ẹ̀ fún un mọ́.Nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀, gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ yóo ti fò lọ.
20 Ìwárìrì á bò ó mọ́lẹ̀ bí ìkún omi,ní alẹ́, ìjì líle á gbé e lọ.
21 Afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn á fẹ́ ẹ sókè,á sì gbé e lọ,á gbá a kúrò ní ipò rẹ̀.