12 A máa da ète àwọn alárèékérekè rú,kí wọn má baà lè yọrí ètekéte wọn.
13 Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n ninu àrékérekè wọn;ó sì mú ète àwọn ẹlẹ́tàn wá sópin.
14 Òkùnkùn bò wọ́n ní ọ̀sán gangan,wọ́n ń fọwọ́ tálẹ̀ lọ́sàn-án bí ẹnipé òru ni.
15 Ṣugbọn Ọlọrun gba aláìníbaba kúrò lọ́wọ́ wọn,ó gba àwọn aláìní kúrò lọ́wọ́ àwọn alágbára.
16 Nítorí náà, ìrètí ń bẹ fún talaka,a sì pa eniyan burúkú lẹ́nu mọ́.
17 “Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí Ọlọrun bá bá wí,nítorí náà, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olodumare.
18 Ó ń ṣá ni lọ́gbẹ́,ṣugbọn ó tún ń dí ọgbẹ́ ẹni.Ó ń pa ni lára,ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ ló tún fi ń ṣe ìwòsàn.