1 WỌNYI si li awọn ti o tọ̀ Dafidi wá si Siklagi, nigbati o fi ara rẹ̀ pamọ, nitori Saulu ọmọ Kiṣi: awọn wọnyi si wà ninu awọn akọni ti nṣe oluranlọwọ ogun na.
2 Nwọn le tafa, nwọn si le fi ọwọ ọtún ati ọwọ ọ̀si sọ okuta, ati fi ọrun tafa, ani ninu awọn arakunrin Saulu ti Benjamini.
3 Ahieseri ni olori, ati Joaṣi, awọn ọmọ Ṣemaa ara Gibea; ati Jesieli ati Peleti, awọn ọmọ Asmafeti; ati Beraka, ati Jehu ara Anatoti,
4 Ati Ismaiah ara Gibeoni, akọni ninu awọn ọgbọ̀n, ati lori ọgbọ̀n (enia) ati Jeremiah, ati Jahasieli, ati Johanani, ati Josabadi ara Gedera.