13 Jeremiah ẹkẹwa, Makbanai ẹkọkanla.
14 Awọn wọnyi li awọn ọmọ Gadi, awọn olori ogun: ẹniti o kere jù to fun ọgọrun enia, ati ẹniti o pọ̀ju to fun ẹgbẹrun.
15 Wọnyi li awọn ti o gòke odò Jordani li oṣù ekini, nigbati o kún bò gbogbo bèbe rẹ̀; nwọn si le gbogbo awọn ti o wà li afonifoji ninu ila-õrùn, ati niha iwọ-õrùn.
16 Ninu awọn ọmọ Benjamini ati Juda si tọ Dafidi wá lori òke.
17 Dafidi si jade lọ ipade wọn, o si dahun o si wi fun wọn pe, Bi o ba ṣepe ẹnyin tọ̀ mi wá li alafia lati ràn mi lọwọ, ọkàn mi yio ṣọkan pẹlu nyin: ṣugbọn bi o ba ṣepe ẹnyin wá lati fi mi hàn fun awọn ọta mi, nigbati ẹbi kò si lọwọ mi, ki Ọlọrun awọn baba wa ki o wò o, ki o si ṣe idajọ.
18 Nigbana ni ẹmi bà lé Amasai, ti iṣe olori awọn ọgbọn na, wipe, Tirẹ li awa, Dafidi, tirẹ li a si nṣe, iwọ ọmọ Jesse: alafia! alafia ni fun ọ! alafia si ni fun awọn oluranlọwọ rẹ; nitori Ọlọrun rẹ ni nràn ọ lọwọ. Dafidi si gbà wọn, o si fi wọn jẹ olori ẹgbẹ-ogun.
19 Ninu ẹyà Manasse si ya si ọdọ Dafidi, nigbati o ba awọn ara Filistia wá lati ba Saulu jagun, ṣugbọn nwọn kò ràn wọn lọwọ: nitori awọn olori awọn ara Filistia, nigbati nwọn gbero, rán a lọ wipe, Ti on ti ori wa ni on o fi pada lọ si ọdọ Saulu oluwa rẹ̀.