1. Kro 12:17-23 YCE

17 Dafidi si jade lọ ipade wọn, o si dahun o si wi fun wọn pe, Bi o ba ṣepe ẹnyin tọ̀ mi wá li alafia lati ràn mi lọwọ, ọkàn mi yio ṣọkan pẹlu nyin: ṣugbọn bi o ba ṣepe ẹnyin wá lati fi mi hàn fun awọn ọta mi, nigbati ẹbi kò si lọwọ mi, ki Ọlọrun awọn baba wa ki o wò o, ki o si ṣe idajọ.

18 Nigbana ni ẹmi bà lé Amasai, ti iṣe olori awọn ọgbọn na, wipe, Tirẹ li awa, Dafidi, tirẹ li a si nṣe, iwọ ọmọ Jesse: alafia! alafia ni fun ọ! alafia si ni fun awọn oluranlọwọ rẹ; nitori Ọlọrun rẹ ni nràn ọ lọwọ. Dafidi si gbà wọn, o si fi wọn jẹ olori ẹgbẹ-ogun.

19 Ninu ẹyà Manasse si ya si ọdọ Dafidi, nigbati o ba awọn ara Filistia wá lati ba Saulu jagun, ṣugbọn nwọn kò ràn wọn lọwọ: nitori awọn olori awọn ara Filistia, nigbati nwọn gbero, rán a lọ wipe, Ti on ti ori wa ni on o fi pada lọ si ọdọ Saulu oluwa rẹ̀.

20 Bi on ti lọ si Siklagi, ninu awọn ẹya Manasse ya si ọdọ rẹ̀, Adna, ati Josabadi, Jediaeli, ati Mikaeli, ati Josabadi ati Elihu, ati Sittai, awọn olori ẹgbẹgbẹrun ti iṣe ti Manasse.

21 Nwọn si ràn Dafidi lọwọ si ẹgbẹ ogun na; nitori gbogbo wọn ni akọni enia, nwọn si jẹ olori ninu awọn ọmọ-ogun.

22 Nitori li akokò na li ojojumọ ni nwọn ntọ Dafidi wá lati ran a lọwọ, titi o fi di ogun nla, gẹgẹ bi ogun Ọlọrun.

23 Eyi ni iye awọn enia na ti o hamọra tan fun ogun, ti nwọn si tọ̀ Dafidi wá si Hebroni, lati pa ijọba Saulu da si ọdọ rẹ̀ gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.