24 Awọn ọmọ Juda ti ngbe asa ati ọ̀kọ, jẹ ẹgbãta enia o le ẹgbẹrin, ti o hamọra tan fun ogun.
25 Ninu awọn ọmọ Simeoni, akọni enia fun ogun ẹ̃dẹgbarin o le ọgọrun.
26 Ninu awọn ọmọ Lefi, ẹgbãji o le ẹgbẹta.
27 Jehoiada olori fun Aaroni, ẹgbẹ̃dogun enia o le ẽdẹgbẹrin si wà pẹlu rẹ̀.
28 Ati Sadoku, akọni ọdọmọkunrin, ati ninu ile baba rẹ̀ olori mejilelogun.
29 Ati ninu awọn ọmọ Benjamini, awọn arakunrin Saulu ẹgbẹ̃dogun: nitori titi di isisiyi, ọ̀pọlọpọ ninu wọn li o ti ntọju iṣọ ile Saulu.
30 Ati ninu awọn ọmọ Efraimu ẹgbãwa o le ẹgbẹrin, akọni ọkunrin, enia olorukọ ni nwọn ni ile baba wọn.