40 Lati ma ru ẹbọ sisun si Oluwa lori pẹpẹ ẹbọ sisun nigbagbogbo li owurọ ati li alẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti a kọ ninu ofin Oluwa, ti o pa li aṣẹ fun Israeli;
41 Ati pẹlu wọn Hemani ati Jedutuni, ati awọn iyokù ti a yàn, ti a si pe li orukọ, lati ma fi ìyin fun Oluwa, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai;
42 Ati pẹlu wọn Hemani ati Jedutuni pẹlu ipè ati kimbali fun awọn ti yio ma pariwo, ati pẹlu ohun èlo orin Ọlọrun. Awọn ọmọ Jedutuni li awọn adena.
43 Gbogbo awọn enia si lọ olukuluku si ile rẹ̀: Dafidi yipada lati sure fun ile rẹ̀.